Sunday, May 17, 2015

ORO ISITI AKEWI

Oro Isiti Akewi

Akole: Ohun to ba gbin lo maa ka

Ewi

Ki lo n be nigbo to un dun mawuru mawuru. Bi o pa ni je ko kuku pa ni je bi o si pa ni je ko ma se pa ni je. Amo ko ye dun mawuru mawuru mo ni mo. E gbo na, ta lo gun yan fun yin to ni tobe o soro eyin tee tafa soke tee yido bori. Eyin tee yo tan tee ti kongo bolu te n so wipe bamubamu ni mo yo emi o mo pebi n pomo eni koo kan. Eyin te n korin 'do or die'. Tee ri yan tan tee ni tobe o soro. Tee ni bi 'lu ba le baje ko baje. E n ko 'rin bi 'lu ba le fo ko fo. E ti gbagbe Orisa Oke to fowo leran to n woye omo adari hunrun. B'oba aye o ri o torun ma n wo o. Hunnnn. Atubotan lo ja ju. Atubo awon kan lati ri yii, tawon to n bo la o mo. Iyato gedegbe lo n be laarin eni ti gbogbo ara re n soro alaafia ati eni to n wi pe bogun ba le de ko de. Eda Adamo e je ka sora si wa hu. Ka mo boja je, kaaa tun ba le je. Eni a n wo eeeee mo gbodo woran. Oba mewa igba mewa ni ile aye. Hausa lo so wipe seriki n goma, samani goma. Ko si ohun taa mu wa ye, ko si ohun ta mu lo. Te ba ro pe e ti seyi e mu je. Hehe hun hun ohun tee se lee maa ka bi ogo ba ti n je toluwa. Oba ti ko si leyin awon olote. Enikan o l e gbin ila ko ka alubosa bee ni e ni kan ko lee gbin isu ko ka agbado. Ere mi n bo kankan loluwa wi, esan si n be lodo mi. Ohun ni Olorun esan yio si san fun onikaluku gege bii ise owo re. What you sow is what you will reap. Esan n bo louwa wii. Te mi ni esan. Esan si ni akobi Olodumare. Ohun to ba gbin sohun lo de maa ka o, maa se gbagbe sikasika ko ranti ojo ola. Ojo te o sile bora. Te o wa dewure jele jele. Te o wa dagutan jeka jeka. Esan a de esan n bo wa o esan a deeeeeeeeeeeeee. Gbogbo atata omo Yoruba e ba mi gbayi yewo. Mo so yi mo duro naa o tun digba kan na.